Ṣé lóòótọ́ ni Saudi fòfin de físà fún àwọn ọmọ Naijiria tó fẹ́ ẹ́ ṣe Hajj 2025?

Aworan awọn Musulumi rẹpẹtẹ ni Kaabah, Meka

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Wẹrẹ ni iroyin kan gba ori afẹfẹ nibẹrẹ ọsẹ yii, pe orilẹede Saudi Arabia ti fofin de awọn ọmọ Naijiria ati awọn orilẹede mẹtala miran to ba fẹẹ rin irin ajo lọ si Mecca, fun Hajj ọdun 2025.

Awọn orilẹ-ede ti ọrọ naa kan ni N, India, Pakistan, Bangladesh, Egypt, Indonesia, Iraq, Jordan, Algeria, Sudan, Ethiopia, Tunisia, Yemen, ati Morocco.

Iroyin naa sọ pe awọn eeyan to ba ni fisa ti wọn fi le ṣe Umurah, ti okoowo tabi ti mọlẹbi ni ọrọ naa kan.

Bakan naa ni awọn eeyan kan wa ti wọn maa n taku si Mecca lẹyin ti asiko to yẹ ki wọn kuro nibẹ ti pe, to si ti le pẹlu.

Nitori iru wọn ni wọn ni iroyin to n lọ lori ayelujara sọ pe, Saudi Arabia ṣe gbe igbesẹ yii.

Kíni ìjọba Saudi sọ gan-an?

Aworan awọn Musulumi to n sọko ni Meka

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Nigba to n fesi si iroyin naa, awọn alaṣẹ ilẹ Saudi Arabia, sọ pe awọn ko fi atẹjade kankan sita to n kede fifi ofin de Naijiria ati awọn orilẹede mẹtala miran.

Gẹgẹ bi ileeṣẹ iroyin The Cable ṣe wi, ẹka to n ri si irinajo ni Saudi, tako iroyin naa, wọn ni ofege ni.

Ẹka ọhun ṣalaye pe atẹjade to n ṣalaye nipa bi irinajo Haji ọdun 2025 yoo ṣe ri loun fi sita.

O ni ko sọhun to jọ fifi ofin de Naijiria tabi awọn orilẹ mẹtala mi-in.

"A ko gba ẹnikẹni to ba ni fisa arinrinajo lọwọ lati ṣe Hajj, wọle tabi duro si Makkah laaarin ọjọ akọkọ oṣu 01 Thul Quda si ọjọ kẹrinla oṣuThul Hijjah 1446 AH .

"Awọn ọjọ yii jẹ ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Kẹrin, si ọjọ kọkanla, oṣu Kẹfa ọdun 2025. (29 April - 11 June 2025 AD)"

Ẹka arinrinajo Saudi lo ṣalaye bẹẹ.

Iwe arinrinajo (fisa) ti wọn maa n fun awọn to ba fẹẹ ṣe Haji, wa lọtọ, oun ni wọn maa n fun awọn to ba fẹẹ di Alaaji/ Alaaja.

Oṣu Kejila ninu onka ọdun awọn Musulumi nikan lo si wa fun.

Eyi ni Saudi n ṣalaye pe o yẹ ki wọn ni lọwọ.

Musulumi to ba fẹẹ lọ si Saudi Arabia lati ṣiṣe Haji yoo gba fisa yii, yatọ si ti awọn to kan fẹẹ ṣabẹwo afẹ sibẹ lasan lasiko ti iṣẹ Haji ko si.

Iru eyi ni Umrah ti eeyan le lọ nigbakigba.

Ìjọba àpapọ̀ Naijiria kín Saudi lẹ́yìn

Lati kin Saudi Arabia lẹyin, ijọba apapọ Naijiria naa fi atẹjade sita lọjọ keje, oṣu Kẹrin 2025 yii.

Minisita to n ri si ọrọ ilẹ okeere, Yusuf Tuggar, ṣalaye ninu atẹjade naa pe Naijiria ko si ninu awọn orilẹede to n koju aile wọle si Saudi lati ọjọ kẹtala, oṣu Kẹrin, 2025.

Atẹjade ti Alkasim Abdulkadir, Amugbalẹgbẹẹ pataki fun Tuggar, fi sita, ṣalaye pe:

"Awọn ti wọn ba mu fisa arinrinajo afẹ dani lasiko Haji ni ọrọ n ba wi.

"Wọn ko le ṣiṣẹ Haji, wọn ko si le wọ Meka tabi duro nibẹ laaarin April 29 si June 11.

"Fisa Haji nikan ni awọn to fẹẹ ṣe Haji le fi wọle laaarin asiko naa"

Ijọba Naijiria rọ awọn eeyan lati ma ṣe gba iroyin to le da irin ajo wọn ru gbọ.

Wọn ni ki wọn kan si ẹka to n ri si irinajo ni ti ododo.

Ìyàtọ̀ wo ló wa láàárín Hajj àti Umurah?

Aworan awọn Musulumi rẹpẹtẹ ni Meka

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Gẹgẹ bi awọn onimọ ẹsin Islam ṣe ṣalaye, Umurah jẹ irinajo ti awọn Musulumi maa n ṣe lọ si orilẹede Saudi Arabia fun ẹsin.

Oun ni wọn maa n pe ni Haji kekeke.

Umurah ko ni asiko kan pato, igbakugba ti eeyan ba ti lagbara rẹ lo le lọ lati ṣe isin ni Meka, ko ṣaa ma ti jẹ asiko ti iṣẹ Haji n lọ lọwọ.

Irinajo Haji ni tiẹ ki i waye bi ko ba di oṣu Kejila oju ọrun ti awọn Musulumi fi n ṣe onka ọdun.

Ninu Haji ni wọn ti maa n sa Safar ati Marwa ju, ti wọn yoo maa kiri Kaaba, ti wọn yoo gun oke Arafah, sọko mọ Aṣetaani ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Wọn maa n gbe Ihram ninu Umurah, wọn yoo yi Kaaba po naa, ṣugbọn ko da bii ti iṣẹ Haji.

Mina, Arafat, and Muzdalifah, gbogbo awọn aaye yii ni awọn to ba n ṣe Haji yoo ti pẹ, ti wọn yoo maa bẹ Oluwa.

Iyatọ miran ni pe, Umurah ko pọn dandan lati lọ, nitori ko si lara opo ẹsin Islam, nigba ti Haji jẹ opo karun-un ẹsin Islam.

Haji jẹ dandan fun Musulumi to ba lowo rẹ lọwọ, to ni alaafia, to si le ṣeto fun awọn to n jẹ labẹ rẹ, ti ebi ko fi ni i pa wọn ko too ti Haji de.

Ero maa n pọ lasiko Haji ju bo ṣe maa n ri fawọn to n ṣe Umurah lọ.

Anọbi Muhammed, ki ikẹ ati ọla Ọlọun maa ba a, gba awọn Musulumi niyanju lati ṣe Umurah, o kere tan, bi ko ju ẹẹkan lọ ki wọn too jade laye.

Umrah funra rẹ pin si ọna meji

Umrah al-Mufradah – Eyi ti wọn maa n ṣe nigbakigba ninu ọdun, ṣaaju Haji gangan.

Umrah al-Tamattu – Wọn maa n ṣe eyi loṣu kejila; Dhul Hijjah, ki iṣẹ Haji gan-an too bẹrẹ.

Ọjọ kẹjọ si ikejila tabi ikẹta oṣu Dhul Hijjah ni wọn fi n ṣe Haji, o pọ ju ọjọ Umrah lọ.

Umurah ati Haji wa fun lati wa oju rere Allah.

Bi eeyan ba ṣe Umurah lasiko Ramadan, ẹsan ẹni to ṣe Haji ni yoo gba bi ọrọ Ọlọrun Allah.